Imú Eerin
Judith Baker
Wiehan de Jager

Gbogbo ènìyàn mọ̀ pé eerin ní imú gígùn.

1

Ṣùgbọ́n ní àyé àtijọ́, imú eerìn kúrú ó sì tóbi.

2

Lẹ́yìn tí wọ́n bí ọmọ eerin kan. Ó bẹ púpọ̀. Kò sí ẹranko tí kò ní ìbéèrè fún.

3

Ó fẹ́ mọ́ nípa àgùnfọn. Ó bèrè lọ́wọ́ àgùnfọn "Kí ló dé tí o ní ọrùn gígùn?"

4

Bákan náà ní ó bèrè lọ́wọ́ Túrùkí. "Kí lo dé tí ó ni ìhò tí ó ní orí ṣóńṣó?"

5

Ó tún fẹ́ mọ̀ nípa Ọ̀ọ̀nì náà. Ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, "Kí ni àwọn ọ̀ọ̀nì máa ń jẹ fún oúnjẹ alẹ́?"

6

Ẹyẹ Àgbìgbò ọlọ́gbọ́n kan dáa lóhùn, "Tẹ̀lé mi lọ sí odò, níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti rí ohun tí ọ̀ọ̀nì ń jẹ fún oúnjẹ alẹ́."

7

Ọmọ Eerin tẹ̀lé àgbìgbò lọ sí odò.

8

Ó rìn kọjá láàárín àwọn koríkò etí odò láti lè dúró létí odò. Ó wo inú odò. "Níbo ni Ọ̀ọ̀ni wà?"

9

Òkùta kan tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò náà kí i pé "báwo ni?" Ọmọ Eerin náà dáhùn pé "dáádá ni." O ní " ṣe o lè sọ fún mi ohun tí Ọ̀ọ̀nì mán ń jẹ fún oúnjẹ alẹ́?"

10

Òkùta náà dáhùn pé " súnmọ́ ibí yìí, n óò sọ ọ́ fún ẹ." Ọmọ Eerin dorí kodò. Okùta ní "Súnmọ́ ibí dáadáa." Ọmọ Eerin túbọ̀ dorí kodò.

11

Lójijì! À fi pàkà! Ọ̀ọ̀ni di eyín mọ́ imú ọmọ Eerin.

12

Ọmọ Eerin jókòó, ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ di ilẹ̀ mú, ó ń fá imú rẹ̀ kúrò lẹ́nu Ọ̀ọ̀nì. Ṣùgbọ́n Ọ̀ọ̀nì kò ju imú rẹ̀ sílẹ̀.

13

Bí ọmọ Eerin ṣe ń fa imú rẹ̀ kúrò lẹnu Ọ̀ọ̀ni, ní imú rẹ̀ ń gùn sí, imú rẹ̀ ń gùn lọ. Kò pẹ́, ọmọ Eerin ṣubú. "Kòròbàtà!"

14

Imú ọmọ Eerin tí ó kúrú tẹ́lẹ̀ tí gùn jádé.

15

Imú rẹ̀ gùn gan-an ni, kódà ó lè fi imú rẹ̀ já èèso láti ara ẹ̀ka-igi tí ó ga fíofío. Títí di òní, Eerin ní imú ti ó gùn tí ó sì wúlò fún un.

16
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Imú Eerin
Author - Judith Baker, Lorato Trok
Translation - Ṣẹ́gun Ṣóẹ̀tán
Illustration - Wiehan de Jager
Language - Yoruba
Level - First sentences