Kíka Àwọn Ẹranko
Zanele Buthelezi
Rob Owen

Erin kan fẹ́ lẹ mu omi.

1

Àgùfọn méjì fẹ́ lọ mu omi.

2

Ẹfọ̀n mẹ́ta àti ẹyẹ mẹ́rin fẹ́ lọ mu omi.

3

Ẹtu márùnún àti túrùkú mẹ́fà ń rìn lọ sí ibi omi.

4

Sẹ́bírà méje ń sáré lọ mu omi.

5

Kọ̀ǹkọ̀ mẹ́jọ àti ẹja mẹ́sànàn ń wẹ̀ nínú omi.

6

Kìnìún kan bú ramúramù. Òun náà fẹ́ mu omi Tani ń bẹ̀rù kìnìún?

7

Erin kan ń mu omi pẹ̀lú kìnìún.

8
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Kíka Àwọn Ẹranko
Author - Zanele Buthelezi, Thembani Dladla, Clare Verbeek
Translation - Ṣẹ́gun Ṣóẹ̀tán
Illustration - Rob Owen
Language - Yoruba
Level - First words