Ọkùnrin Gíga Púpọ̀ Kan
Cornelius Gulere
Catherine Groenewald

Ọkọ́ rẹ̀ kúrú jù.

1

Ọ̀nà ilẹ̀kùn rẹ̀ kéré jù.

2

Ibùsùn rẹ̀ kúrú jù.

3

Kẹ̀kẹ́ rẹ̀ kúrú jù.

4

Ọkùnrin yìí ga jù!

5

Ó ṣe ọwọ ọkọ́ gígùn púpọ̀ kan.

6

Ó ṣe ara ilẹ̀kùn gíga púpọ̀.

7

Ó ṣe ibùsùn gígùn púpọ̀ kan.

8

Ó ra kẹ̀kẹ́ gíga púpọ̀ kan.

9

Ó jòkó lórí aga gíga kan. Ó jẹun pẹ̀lú fọ́ọ̀kì gígùn kan.

10

Ó kúrò ní ilé rẹ̀, o sì gbé ní igbó ńlá kan. Ó gbé fún ọdún púpọ̀.

11
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ọkùnrin Gíga Púpọ̀ Kan
Author - Cornelius Gulere
Translation - Taiwo Ẹhinẹni
Illustration - Catherine Groenewald
Language - Yoruba
Level - First sentences