Èso Kékeré Kan: Ìtàn Tí Wangari Maathai
Nicola Rijsdijk
Maya Marshak

Ní abúlé kan lórí Òkè Kenya ní Ìlà-oòrùn Afrika, ọmọ kékeré kan ṣiṣẹ́ nínú oko pẹ̀lú màmá rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Wangari.

1

Wangari fẹ́ràn láti wà ní ìta. Ní ọgbà ilé oúnjẹ ẹbí rẹ̀, ó tu ilẹ̀ pẹ̀lú àdá rẹ̀. Ó fi àwọn èso kékeré sínú ilẹ̀.

2

Àkókò tí ó fẹ́ràn ni ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí alẹ́ bá ti lẹ́ jù, Wangari mọ̀ pé àkókò ti tó láti lọlé. Ó máa gba ọ̀nà tínínrín inú oko tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò tí ó bá tí ń padà lọlé.

3

Wangari jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kò lè dúró títí tí ó máa fi lọ sí ilé-ìwé. Ṣùgbọ́n màmá àti bàbá rẹ̀ fẹ́ jẹ́kí ó dúró sílé láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọ̀dún méje, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin sọ fún àwọn òbí wọn kí wọ́n jẹ́ kí ó lọ sí ilé-ìwé.

4

Ó fẹ́ràn láti kàwé! Wangari kọ́ oríṣiríṣi nǹkan nínú ìwé tí ó kà. Ó ṣe dáradára ní ilé-ìwé débi pé wọ́n pè wá sí ìlú Amerika láti kàwé. Inú Wangari dùn gán an ni! Ó fẹ́ mọ̀ si nípa gbogbo ayé.

5

Ní Yunifásítì kan ní ìlú Amerika, Wangari kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tuntun. Ó kọ́ nípa bí àwọn ewé ṣe ń dàgbà. Ó rántí bí òun ṣe dàgbà: bí òun ṣe ń ṣeré pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ lábẹ́ àwọn igi inú igbó Kenya.

6

Bí ó ṣe ń kàwé si ni ó ń ri bí òun ṣe fẹ́ràn àwọn ènìyàn Kenya. Ó fẹ́ jẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ àtí òmìnira. Bí ó ṣe ń kàwé si ni ó ń rántí ilé rẹ̀ ní Afrika.

7

Nígbá tí ó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó padà sí Kenya. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè rẹ̀ ti yípadà. Àwọn oko ńlá ti pọ̀si nílẹ̀. Àwọn obìnrin kò ní igi láti fi dáná. Àwọn ènìyàn tòṣì. Ebi sì ń pa àwọn ọmọdé.

8

Wangari mọ nǹkan tí óun lè ṣe. Ó kọ́ àwọn obìnrin láti gbin igi pẹ̀lú èso. Àwọn obìnrin náà ta àwọn igi náà, wọ́n sì lo owó tí wọ́n rí láti fi tọ́jú ẹbí wọn. Inú àwọn obìnrin náà dùn púpọ̀. Wangari ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè borí wàhálà wọn.

9

Lẹ́hìn àkókò púpọ̀, àwọn igi tuntun náà dàgbà sí igbó, àwọn odò náà sì padà. Gbogbo ènìyàn ní Afrika ni ó gbọ́ nǹkan tí Wangari ṣe. Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn igi ni ó ti dàgbà nípasẹ èso ti Wangari.

10

Wangari tí ṣiṣẹ́ gan an. Gbogbo ènìyàn káàkiri àgbáyé ni ó mọ̀, wọ́n sì fun ní ẹ̀bùn ńlá kan. Wọ́n ń pè é ní ẹ̀bùn ti Nobel Peace, òun sì ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ gbà á.

11

Wangari kú ní ọ̀dún 2011, ṣùgbọ́n a lè ronú nípa rẹ̀ nígbàkígbà tí a bá rí igi arẹwà kan.

12
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Èso Kékeré Kan: Ìtàn Tí Wangari Maathai
Author - Nicola Rijsdijk
Adaptation - Taiwo Ẹhinẹni
Illustration - Maya Marshak
Language - Yoruba
Level - First paragraphs